4. Ábúsálómù a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan báà lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.”
5. Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ ọn láti tẹ́ribá fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dì í mú, a sì fí ẹnu kò ó lẹ́nú.
6. Irú ìwà bàyìí ni Ábúsálómù sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sọ́dọ̀ rẹ̀.
7. Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Ábúsálómù sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hébírónì.
8. Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Géṣúrì ní Síríà pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jérúsálẹ́mù, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”
9. Ọba sì wí fún un pé, “Má a lọ ní àlàáfíà.” Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hébúrónì.
10. Ṣùgbọ́n Ábúsálómù rán àmì sáàrin gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ábúsálómù jọba ní Hébúrónì.’ ”
11. Igba ọkùnrin sì bá Ábúsálómù ti Jérúsálẹ́mù jáde, nínú àwọn tí a ti pè; wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkankan.
12. Ábúsálómù sì ránṣẹ́ pe Áhítófélì ará Gílónì, ìgbìmọ̀ Dáfídì, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Gílónì, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Ábúsálómù.