2 Sámúẹ́lì 13:36-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sòkè, wọ́n sì sunkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá.

37. Ábúsálómù sì sá, ó sì tọ Támáì lọ, ọmọ Ámíhúdù, ọba Gésúrì. Dáfídì sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lojojúmọ́.

38. Ábúsálómù sì sá, ó sì lọ sí Géṣúrì ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta.

39. Ọkàn Dáfídì ọba sì fà gidigidi sí Ábúsálómù: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Ámúnónì: ó sáà ti kú.

2 Sámúẹ́lì 13