18. Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan làra rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúndíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.
19. Támárì sì bu èérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ.
20. Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Támárì sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
21. Ṣùgbọ́n nígbà tí Dáfídì ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi.
22. Ábúsálómù kò sì bá Ámíúnónì sọ nǹkan rere, tàbí búburú: nítorí pé Ábúsálómù kóríra Ámúnónì nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀.