16. Ó sì ṣe nígbà tí Jóábù ṣe àkíyèsí ìlú náà, ó sì yan Úráyà sí ibi kàn ní ibi tí òun mọ̀ pé àwọn alágbára ọkùnrin ń bẹ níbẹ̀.
17. Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Jóábù jà: díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, Ùráyà ará Hítì sì kú pẹ̀lú.
18. Jóábù sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dáfídì.
19. Ó sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́ náà pé, “Nígbà tí iwọ bá sì parí àti máa ro gbogbo nǹkan ogun náà fún ọba.
20. Bí ó bá ṣe pé, ibinú ọba bá fàru, ti òun sì wí fún ọ pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fí súnmọ́ ìlú náà láti bá wọn jà, ẹ̀yin kò mọ̀ pé wọn ó tafà láti orí odì wá.
21. Ta ni ó pa Ábímélékì ọmọ Jerubu-Bésétì? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tébésì? Èé ha ti rí tí ẹ̀yín fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún-un pé, Ùráyà ìránṣẹ́ rẹ ará Hítì kú pẹ̀lú.’ ”
22. Ìránṣẹ́ náà sì lọ, ó sì wá, ó sì jẹ́ gbogbo iṣẹ́ tí Jóábù rán an fún Dáfídì.