6. “Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, mo wà ní orí òkè Gílíbóà níbẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.
7. Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, kí ni mo lè ṣe?
8. “Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’“Mo dáhùn pé, ‘Ará a Ámálékì,’
9. “Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láàyè.’
10. “Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún Olúwa mi.”
11. Nígbà náà ni, Dáfídì àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya.