2 Sámúẹ́lì 1:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Dáfídì sì fi orin arò yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Ṣọ́ọ̀lù àti lórí Jónátanì ọmọ rẹ̀,

18. Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Júdà ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jáṣárì):

19. “Ogo rẹ, Ísírẹ́lì ni a pa ní òkè gíga rẹ.Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!

20. “Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gátì,ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Áṣíkélónì,kí àwọn ọmọbìnrin Fílístínì má bá à yọ̀,kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má baà dunnú.

2 Sámúẹ́lì 1