13. Wọ́n ṣe gírì, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní órí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ipè, wọ́n sì kígbe, “Jéhù jẹ ọba!”
14. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù ọmọ Jéhósáfátì, ọmọ Nímsì, dìtẹ̀ sí Jórámù. (Nísinsìnyí Jórámù àti gbogbo Ísírẹ́lì ti ń dábòbò Ramoti-Gílíádì nítorí Hásáélì ọba Árámù:
15. Ṣùgbọ́n ọba Jórámù ti padà sí Jéṣérẹ́lì láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Árámù ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hásáélì ti Árámù). Jéhù wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jéṣérẹ́lì.”
16. Nígbà náà ó wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jésérẹ́lì, nítorí Jórámù ń sinmi níbẹ̀ àti ọba Áhásáyà tilọ láti lọ wò ó.
17. Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jésérẹ́lì, rí ọ̀wọ́-ogun Jéhù tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.”“Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Jórámù pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”