2 Ọba 7:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Àwọn aṣọ́bodè náà pariwo ìròyìn náà, wọ́n sì sọ nínú ààfin.

12. Ọba sì dìde ní ùru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣọ fún yín ohun tí àwọn ará Ṣíríà tí ṣe fún wa. Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sá pamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, ‘Wọn yóò jáde lóòtọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè àwa yóò yí wọ inú ìlú lọ.’ ”

13. Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé, “Mú ọkùnrin díẹ̀ mú márùnún lára àwọn ẹsin tí wọ́n fi sílẹ̀ nínú ìlú. Ìwà wọn yóò dà bí gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì tí ó kù níbẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóò dà bí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì, yìí nìkan tí a run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ jẹ́ kí a rán wọn lọ láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”

14. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan kẹ̀kẹ́ méjì pẹ̀lú ẹsin wọn, ọba sì ránsẹ́ tọ ogun àwọn ará Síríà lẹ́yìn ó pàṣẹ fún àwọn awakọ̀ pé, “Ẹ lọ kí e lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”

15. Wọ́n sì tẹ̀lé wọn títí dé Jọ́dánì, wọ́n sì rí gbogbo ọ̀nà kún fún agbádá pẹ̀lú ohun èlò tí ará àwọn Ṣíríà gbé sọnù ní yàrá wọn. Ìránsẹ́ náà padà ó sì wá sọ fún ọba.

2 Ọba 7