2 Ọba 3:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Nígbà tí ọba Móábù rí i wí pé ogun náà le ju ti òun lọ, ó mú idà pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọkùnrin (700) onídà láti jà pẹ̀lú ọba Édómù, ṣùgbọ́n wọn kò yege.

27. Nígbà náà ó mú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀, tí kò bá jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba, ó sì fi rú ẹbọ sísun ní orí ògiri ìlú. Wọ́n sì bínú lórí Ísírẹ́lì púpọ̀púpọ̀; wọ́n yọ́ kúrò wọ́n sì padà sí ìlú wọn.

2 Ọba 3