2 Ọba 20:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Heṣekáyà ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú. Wòlíì Àìsáyà ọmọ Ámósì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú; o kò níí gbádùn.”

2. Heṣekáyà yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí Olúwa pé,

3. “Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Heṣekáyà sunkún kíkorò.

4. Kí ó tó di wí pé Àìṣáyà jáde kúrò ní àárin àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé.

2 Ọba 20