13. Níbo ni ọba Hámátì wa, ọba Árípádì, ọba ìlú Séfárífáímù, ti Hénà, tàbí ti Ífà gbé wà?”
14. Heṣekíàyà gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ ṣíwájú Olúwa.
15. Heṣekáyà gbàdúrà sí Olúwa: “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ń gbé ní àárin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.
16. Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú ù rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Ṣenakérúbù tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.
17. “Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Ásíríà ti pa orílẹ̀ èdè wọ̀nyìí run àti ilẹ̀ wọn.