19. Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Heṣekáyà pé:“ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ: Lórí kí ni ìwọ ń dá ìgbóyà rẹ̀ yìí?
20. Ìwọ wí pé ìwọ ni ẹ̀tà àti ti ogun alágbára ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo nìkan, lórí ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi?
21. Wò ó Nísinsìn yìí ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Éjíbítì, ẹ̀rún igi pẹlẹbẹ ọ̀pá ìyè lórí ọ̀pá, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ọkùnrin tí ó sì pa á lára tí ó bá fi ara tìí Irú rẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.
22. Tí ìwọ bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa Ọlọ́run.” Òun ha kọ́ ní ẹnìkan náà tí ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tí Heṣekáyà mú kúrò, tí ó wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé, “O gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí ní Jérúsálẹ́mù”?