2 Ọba 17:27-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà náà ọba Ásíríà pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Ṣamáríà lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí Olúwa ilẹ̀ náà béèrè.”

28. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samáríà wá gbé ní Bétélì ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa.

29. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀ èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Ṣamáríà ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì.

2 Ọba 17