2 Ọba 15:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jéhù jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”

13. Ṣálúmù ọmọ Jábésì di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà ọba Júdà, ó sì jọba ní Ṣamáríà fún oṣù kan.

14. Nígbà náà Ménáhémù ọmọ Gádì lọ láti Tírísà sí Ṣamáríà. Ó dojúkọ Ṣalúmù ọmọ Jábésì ní Samáríà, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

15. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣalúmù, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.

16. Ní ìgbà tí Ménáhémù ń jáde bọ̀ láti Tíríṣà, ó dojúkọ Tífíṣà àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, Nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tífsà kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún.

17. Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Ásáríyà ọba Júdà, Ménáhémù ọmọ Gádì di ọba Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní Samáríà fún ọdún mẹ́wàá.

2 Ọba 15