2 Kọ́ríńtì 8:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lé rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìyìnrere ẹlòmírán.

9. Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di talákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀.

10. Àti nínú èyí ni mo fí ìmọ̀ràn mi fún yín: nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú.

2 Kọ́ríńtì 8