2 Kọ́ríńtì 4:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dàámú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù.

9. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run.

10. Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jésù Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jésù hàn pẹ̀lú lará wa.

2 Kọ́ríńtì 4