2 Kọ́ríńtì 11:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Éfà jẹ́ nípaṣẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín sáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajìn fún Kírísítì.

4. Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jésù mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.

5. Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn ní ohunkohun sí àwọn àgbà Àpósítélì.

2 Kọ́ríńtì 11