2 Kíróníkà 7:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Sólómónì sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ọrẹ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé Olúwa.

2. Àwọn àlùfáà wọn kò sì le wo ilé Olúwa náà nítorí pé ògo Olúwa kún un.

2 Kíróníkà 7