2 Kíróníkà 5:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́.

4. Gbogbo àwọn àgbààgbà Isirẹ́lì sì wá, àwọn ọmọ Léfì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa.

5. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ni ó mú wọn gòkè wá;

6. Nígbà náà ni ọba Sólómónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò leè kà tán rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò leè mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó.

7. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀ri ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.

2 Kíróníkà 5