2 Kíróníkà 4:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó ṣe pọnunpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúṣù àti márùn ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ọrẹ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo òkun fún fífọ nǹkan.

7. Ó ṣe ìgbe fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúsù àti márùn ún ní ìhà àríwá.

8. Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúṣù àti márùn ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rún ọpọ́n ìbùwọ̀n wúrà.

9. Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ.

10. Ó gbé òkun náà ka orí ìhà gúsù ní ẹ̀bá Igun gúsù àríwá.

2 Kíróníkà 4