2 Kíróníkà 27:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jótamù, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.

8. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

9. Jótamù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dáfídì, Áhásì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

2 Kíróníkà 27