6. Ó sì lọ sí ogun lórí Fílístínì ó sì wó odi Gátì lulẹ̀, Jábìnè àti Ásídódù. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Ásídódù àti níbì kan láàrin àwọn ará Fílístínì.
7. Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lóri àwọn ará Fílístínì àti Árábù tí ń gbé ní Gúrì Bálì àti lórí àwọn ará Méhúmì.
8. Àwọn ará Ámórì gbé ẹ̀bùn wá fún Usíà, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Éjíbítì, nítorí ó ti di alágbára ńlá.
9. Ùsáyà sì kọ́ ìlú sí Jérúsálẹ́mù níbi ẹnu bodè igun, àti nibi ẹnu bodè àfonífojì àti nibi ìṣẹ́po-odi ó sì mú wọn le
10. Ó sì tún ilé ìṣọ́ ihà kọ́, ó sì gbẹ́ kàǹga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbààjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.