2 Kíróníkà 26:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dogún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀.

14. Ùsáyà sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ ogun.

15. Ní Jérúsálẹ́mù ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun tí ó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ihumọ̀ ọlọgbọ́n ọkùnrin fún lílò lórí ilé-ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.

16. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ùsáyà jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìsòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wo ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.

2 Kíróníkà 26