6. Nítorí náà ọba paálásẹ fún Jéhóiádà olorí àlùfáà ó sì wí fún-un pé, “Kí ni ó dé tí o kò, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará Léfì láti mú wá láti Júdà àti Jérúsálẹ́mù, owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Ísírẹ́lì fún àgọ́ ìjẹ́rìí?”
7. Nísinsinyí, àwọn ọmọkùnrin, obìnrin búburú ni Ataláyà ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Báálì.
8. Nípasẹ̀ ọba, a ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa.
9. A ṣe ìkéde ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti bèèrè lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ní ihà.
10. Gbogbo àwọn ènìyàn mú gbogbo ìdá owó ti wọn wá pẹ̀lú ìdùnnú, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún.