2 Kíróníkà 21:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà tí Jéhórámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó pa gbogbo àwọn arákùrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìrin ọba Ìsirẹ́lì.

5. Jéhórámù jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjọ.

6. Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé Áhábù ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìrin Áhábù. Ó ṣe búburú lójú Olúwa.

7. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí Olúwa ti dá fún Dáfídì kì í ṣe ífẹ́ Olúwa láti pa ìdílé Dáfídì run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé.

8. Ní àkókò Jéhórámù, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀.

2 Kíróníkà 21