2 Kíróníkà 20:35-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Nígbà tí ó yá, Jehóṣáfátì ọba Júdà da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Áhásáyà, ọba Ísírẹ́lì, ẹni tí ó jẹ̀bi búburú ìwà.

36. Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan okọ̀ láti lọ sí Táríṣísì, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Ésíonì-Gébérì.

37. Élísérì ọmọ Dáfídì ti Máréṣà sọtẹ́lẹ̀ sí Jóhóṣáfátì, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Áhásáyà, Olúwa yóò pa ohun ti iwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà.

2 Kíróníkà 20