10. Ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wà níwájú rẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé ìlú wọn bóyá ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn tàbí ìyókù òfin pẹ̀lú, paálásẹ ìlànà àti ẹ̀tọ́, ìwọ gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe dẹ́sẹ̀ sí Olúwa bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú yóò sì wá sórí yín, àti sórí àwọn arákùnrin. Ṣe èyi, ìwọ kò sì ní dẹ́ṣẹ̀.
11. “Ámáríyà àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti Olúwa, àti Ṣébádíà ọmọ Íṣímáélì alákòóso ìdílé Júdà, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Léfì pẹ̀lu yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín. Ẹ ṣeé pẹ̀lú ìmọ́kànle, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere.”