2 Kíróníkà 14:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó pa á láṣẹ fún Júdà láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wọn àti láti tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ àti àṣẹ.

5. Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Júdà. Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀.

6. Ó mọ àwọn ìlu ààbò ti Júdà, níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti wà ní àlàáfíà. Kò sí ẹnikẹ́ni ti o jagun pẹ̀lu rẹ̀ nígbà àwọn ọdun wọ̀n yẹn. Nítorí Olúwa fún un ní ìsinmi.

7. “Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí” Ó wí fún Júdà, “Kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ile ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti bèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere.

2 Kíróníkà 14