2 Jòhánù 1:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú àbọ̀.

11. Nítorí ẹni tí ó bá kí i kú àbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.

12. Bí mo ti lẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alabapin pẹ̀lú yín, síbẹ̀èmi kò fẹ́ lo ìwé-ìkọ́wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.

13. Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.

2 Jòhánù 1