2 Jòhánù 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Alàgbà,Sì àyànfẹ́ obìnrin-ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmí nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú;

2. nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.

3. Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlààáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.

4. Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pá àṣẹ fún wa.

2 Jòhánù 1