1 Tímótíù 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. NÍṢÍNṢIN YÌÍ, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èsù.

2. Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkarawọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó.

3. Àwọn tí ń dá-ni-lẹ́kun láti gbéyàwó ti wọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́.

1 Tímótíù 4