1 Tẹsalóníkà 5:23-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Kí Ọlọ́run àlàáfíà pàápàá wẹ̀ yín mọ́, kí ó sì yà yín sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́, títí di ìgbà wíwá Jésù Kírísítì Olúwa wa.

24. Olótítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.

25. Ẹ̀yin ará, ẹ gbàdúrà fún wa.

26. Ẹ gbà ara yín ní ọwọ́ ní orúkọ mi pẹ̀lú ọkàn funfun.

27. Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́ta yìí fún gbogbo àwọn ará.

28. Ki oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín. Àmín.

1 Tẹsalóníkà 5