1 Tẹsalóníkà 5:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ maa lépa èyí tíi ṣe rere láàrin ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.

16. Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo

17. Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo

18. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kírísítì Jésù nítòótọ́.

19. Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́.

20. Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń ìsọtẹ́lẹ̀.

1 Tẹsalóníkà 5