1 Sámúẹ́lì 9:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Sámúẹ́lì, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.

15. Olúwa ti sọ létí Sámúẹ́lì ní ijọ́ kan kí Ṣọ́ọ̀lù ó tó dé pé,

16. “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

1 Sámúẹ́lì 9