1. Ará Bẹ́ńjámínì kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíṣì, ọmọ Ábíélì, ọmọ Sésórì, ọmọ Békórátì, ọmọ Áfíà ti Bẹ́ńjámínì.
2. Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Ṣọ́ọ̀lù, ọ̀dọ̀mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàárin gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì—láti èjìka rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga jú gbogbo àwọn ènìyàn tó kù lọ.
3. Nísinsìn yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù sì sọnù. Nígbà náà, Kíṣì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”