1. Ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì tọ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá.Nísinsìnyìí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde láti lọ bá àwọn Fílístínì jà. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pàgọ́ sí Ebenésérì àti àwọn Fílístínì ní Áfékì.
2. Àwọn Fílístínì mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Ísírẹ́lì, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Fílístínì ṣẹ́gun Ísírẹ́lì wọ́n pa ẹgbàájì ọkùnrin nínú ogun náà (4,000).