13. Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun.
14. Nítorí náà, mo búra sí ilé Élì, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Élì ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”
15. Sámúẹ́lì dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Élì.
16. Ṣùgbọ́n Élì pè é, ó sì wí pé, “Sámúẹ́lì, ọmọ mi.”Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.”