1 Sámúẹ́lì 23:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọ́n sì wí fún Dáfídì pé, “Ṣá wò ó, àwọn ará Fílístínì ń bá ará Kéílà jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.”

2. Dáfídì sì béèré lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Fílístínì wọ̀nyí bí?” Olúwa sì wí fún Dáfídì pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Fílístínì kí o sì gba Kéílà sílẹ̀.”

3. Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dáfídì sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhín yìí ní Júdà; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Kéílà láti fi ojú ko ogun àwọn ara Fílístínì?”

1 Sámúẹ́lì 23