4. Jónátanì sọ̀rọ̀ rere nípa Dáfídì fún Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀.
5. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Fílístínì. Olúwa ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Èéṣe nígbà náà tí ìwọ yóò fi ṣe ohun búburú sí ọkùnrin aláìṣẹ̀ láìnídìí?”
6. Ṣọ́ọ̀lù fetísí Jónátanì, ó sì búra báyìí, “Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láàyè, a kì yóò pa Dáfídì.”
7. Nítorí náà Jónátanì pe Dáfídì, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì sì wà lọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.
8. Lẹ́ẹ̀kàn an sí i ogun tún wá, Dáfídì sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Fílístínì jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀.