1 Sámúẹ́lì 17:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nísinsìn yìí Dáfídì jẹ́ ọmọ ará Éfúrátà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésè, tí ó wá látí Bétílẹ́hẹ́mù ní Júdà, Jésè ní ọmọ mẹ́jọ, ní àsìkò Sáulù ó ti darúgbó ẹni ọdún púpọ̀.

13. Àwọn ọmọ Jésè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Ṣọ́ọ̀lù lọ sí ojú ogun: Èyí àkọ́bí ni Élíábù: Èyí èkejì ni Ábínádábù, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣámínà.

14. Dáfídì ni ó kéré jù nínú wọn. Àwọn àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì tẹ̀lé Ṣọ́ọ̀lù,

15. Ṣùgbọ́n Dáfídì padà lẹ́yìn Ṣọ́ọ̀lù, láti máa tọ́jú àgùntàn baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

1 Sámúẹ́lì 17