7. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù kọlu àwọn Ámálékì láti Háfílà dé Súrì, tí ó fi dé ìlà oòrùn Éjíbítì.
8. Ó sì mú Ágágì ọba Ámálékì láàyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlu gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.
9. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátapáta ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì ní láárí ni wọ́n parun pátapáta.
10. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sámúẹ́lì wá pé:
11. “Èmi káànú gidigidi pé mo fi Ṣọ́ọ̀lù jọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Sámúẹ́lì sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì képe Olúwa ní gbogbo òru náà.