1 Ọba 7:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sólómónì sì lo ọdún mẹ́talá láti fi kọ́ ààfin rẹ̀, ó sì parí gbogbo iṣẹ́ ààfin rẹ̀.

2. Ó kọ́ ilé igbó Lébánónì pẹ̀lú; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́; pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kédárì, àti ìdábú igi kédárì lórí òpó náà.

3. A sì fi igi kédárì tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ̀n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀dógún ní ọ̀wọ́.

4. Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn.

1 Ọba 7