16. Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní ibi mímọ́ jùlọ.
17. Ní iwájú ilé náà, ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́.
18. Inú ilé náà sì jẹ́ Kédárì, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìtàkùn àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ Kédárì; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.
19. Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí májẹ̀mú Olúwa ka ibẹ̀.
20. Nínú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi Kédárì bo pẹpẹ rẹ̀.