1. Sólómónì sì bá Fáráò ọba Éjíbítì dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú-un wá sí ìlú Dáfídì títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹ́ḿpìlì Olúwa, àti odi tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká.
2. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tíì kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa títí di ìgbà náà
3. Sólómónì sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Olúwa nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dáfídì baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga.
4. Ọba sì lọ sí Gíbíónì láti rúbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Sólómónì sì rú ẹgbẹ̀rún ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.
5. Ní Gíbíónì Olúwa fi ara han Sólómónì lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.”