10. Ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà jókòó lórí ìtẹ́ wọn, wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn ní ìta ẹnubodè Samáríà, gbogbo àwọn wòlíì náà sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.
11. Ṣedekíà ọmọ Kénáánà sì ṣe ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Wọ̀nyí ni ìwọ yóò fi kan àwọn ará Árámù títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ ”
12. Gbogbo àwọn wòlíì tó kù sì ń sọtẹ́lẹ̀ ohun kan náà wí pé, “Kọlu Ramoti-Gílíádì, kí o sì ṣẹ́gun.” Wọ́n sì wí pé, “nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”
13. Ìránṣẹ́ tí ó lọ pe Míkáyà wí fún un pé, “Wò ó, ẹnu kan náà ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì fi jẹ́ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ bá ti àwọn tókù mu, kí o sì sọ rere.”
14. Ṣùgbọ́n Míkáyà wí pé, “Bí Olúwa ti wà, ohun tí Olúwa bá sọ fún mi ni èmi yóò sọ fún un.”
15. Nígbà tí ó sì dé, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Míkáyà, ṣé kí a lọ bá Ramoti-Gílíádì jagun, tàbí kí a jọ̀wọ́ rẹ̀?”Ó sì dáhùn wí pé, “Lọ, kí o sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”