8. Ábíjà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì. Áṣà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
9. Ní ogún ọdún Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Áṣà jọba lórí Júdà,
10. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù.
11. Áṣà sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, bí Dáfídì baba rẹ̀ ti ṣe.
12. Ó sì mú àwọn tí ń ṣe panṣágà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò.
13. Ó sì mú Máákà ìyá ìyá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún òrìṣà rẹ̀. Áṣà sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún níbi odò Kídírónì.
14. Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Áṣà pé pẹ̀lú Olúwa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.
15. Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé Olúwa
16. Ogun sì wà láàrin Áṣà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn.
17. Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì sì gòkè lọ sí Júdà, ó sì kọ́ Rámà láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Áṣà ọba lọ.