16. Ogun sì wà láàrin Áṣà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn.
17. Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì sì gòkè lọ sí Júdà, ó sì kọ́ Rámà láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Áṣà ọba lọ.
18. Nígbà náà ni Áṣà mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Bẹni-Hádádì ọmọ Tábírímónì, ọmọ Hésíónì ọba Síríà tí ó ń gbé ní Dámásíkù.
19. Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrin èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrin bàbá mi àti bàbá rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”
20. Bẹni-Hádádì gba ti Áṣà ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì. Ó sì ṣẹ́gun Íjónì, Dánì àti Abeli-Bẹti-Máákà, àti gbogbo Kénérótì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náfútalì.