18. Wọ́n sì sin ín, gbogbo Ísírẹ́lì sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí láti ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Ábíjà wòlíì.
19. Ìyòókù ìṣe Jéróbóámù, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì.
20. Jéróbóámù sì jọba fún ọdún méjìlélógún, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Nádábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
21. Réhóbóámù ọmọ Sólómónì sì jọba ní Júdà. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó sì jọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí Olúwa ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámà, ará Ámónì.