14. Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta (666) ó lé mẹ́fà talẹ́ńtì wúrà,
15. Láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Árábíà, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.
16. Sólómónì ọba sì ṣe igba (200) aṣà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan.
17. Ó sì tún ṣe ọ̀ọ́dúrún (300) aṣà wúrà lílù, pẹ̀lú òṣùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí aṣà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lébánónì.
18. Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ èyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó.
19. Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, èyín rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni irọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìkọ̀ọ̀kan wọn.
20. Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ọ̀kọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí.