1 Kọ́ríńtì 3:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín?

17. Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yín jẹ́.

18. Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n.

1 Kọ́ríńtì 3